Ounje ni mi, emi ni ounje

Àgbè ní mí, oúnje ní mí
Oúnje ní mí, èmi ní oúnje
B’ékòló bá ti júbà ilè, ilè á lanu
Mo júbà bàbá mi Akanni

Baba mi, máa gbó l’ájùlé òrun
Ayé bínú iyò, wón po iyò m’éèpè
Ayé bínú kán-ún, wón so kán-ún s’ómi
Ayé bínú baba mi, wón pa ní aipe ojó
Ayé ò ní se yín, e ò ní sìse

Bí ò bá sí ègé, kí l’a ó máa pè ní gààrì?
Bí ò bá sí igi òpe, kí l’a ó máa pè ní epo?
Bí ò bá sí isu, kí l’a ó máa pè ní iyán?
Bí ò bá sí àgbàdo, kí l’a ó máa pè ní éko?
Bí ò bá sí èlùbó, kí l’a ó máa pè ní ámàlà?
Bí ò bá sí ewa, kí l’a ó máa pè ní moimoi?
Bí ò bá sí Olódùmarè, ta ni a ó máa pè ní Ajani?

About Omoloye Miracle 179 Articles
Omoloye Miracle is a writer, voice over artist, genotype and blood group advocate, ghost writer, counselor, script writer at Remo TV, poet, media coordinator II at Spirit Life Network, content team lead at TASUED Writers Community and founder of Mheerah-dee Drops.

8 Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published.


*